Numbers 11:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí OLUWA nípa ìṣòro wọn. Nígbà tí OLUWA gbọ́ kíkùn wọn, inú bí i, ó sì fi iná jó wọn; iná náà run gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní òpin ibùdó náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN enia na nṣe irahùn, nwọn nsọ ohun buburu li etí OLUWA: nigbati OLUWA si gbọ́ ọ, ibinu rẹ̀ si rú; iná OLUWA si ràn ninu wọn, o si run awọn ti o wà li opin ibudó na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etíìgbọ́ OLÚWA. Ìbúnú OLÚWA sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí, Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ OLÚWA bọ́ sí àárin wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó.