Numbers 11:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose gbọ́ bí àwọn eniyan náà ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ wọn, olukuluku pẹlu àwọn ará ilé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dun Mose, ibinu OLUWA sì ru sí àwọn eniyan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sunkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálukú ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. OLÚWA sì bínú gidigidi. Inú Mósè sì bàjẹ́ pẹ̀lú.