Numbers 11:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Yan aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli mọ̀ ní olórí, kí o sì mú wọn wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí wọ́n dúró pẹlu rẹ níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba Israeli jọ sọdọ mi, ẹniti iwọ mọ̀ pe, nwọn ṣe àgba awọn enia, ati olori wọn; ki o si mú wọn wá si agọ́ ajọ, ki nwọn ki o si duro nibẹ̀ pẹlu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé: “Mú àádọ́rin (70) ọkùnrin nínú àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrin àwọn ènìyàn wá sínú Àgọ́ Ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi.