Numbers 11:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀. N óo mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára rẹ, n óo fi sí wọn lára; kí wọn lè máa ràn ọ́ lọ́wọ́, láti gbé ẹrù àwọn eniyan náà, kí ìwọ nìkan má baà máa ṣe iṣẹ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọkalẹ wá, emi o si bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀: emi o si mú ninu ẹmi ti mbẹ lara rẹ, emi o si fi i sara wọn; nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù awọn enia na, ki iwọ ki o máṣe nikan rù u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú nínú Ẹ̀mi tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà.