Numbers 11:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ óo jẹ ẹran lọ́la. OLUWA ti gbọ́ ẹkún ati ìráhùn yín pé, ‘Ta ni yóo fún wa ní ẹran jẹ, ó sàn fún wa jù báyìí lọ ní ilẹ̀ Ijipti.’ Nítorí náà OLUWA yóo fun yín ní ẹran.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o si wi fun awọn enia na pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ dè ọla, ẹnyin o si jẹ ẹran: nitoriti ẹnyin sọkun li etí OLUWA, wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ? o sá dara fun wa ni Egipti: nitorina ni OLUWA yio ṣe fun nyin li ẹran, ẹnyin o si jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé OLÚWA ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Éjíbítì jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni OLÚWA yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́.