Numbers 11:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose sì sọ fún OLUWA pé, “Àwọn tí wọn tó ogun jà nìkan ninu àwọn eniyan tí mò ń ṣe àkóso wọn yìí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) o sì wí pé o óo fún wọn ní ẹran jẹ fún oṣù kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wipe, Awọn enia na, lãrin awọn ẹniti emi wà, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀; iwọ si wipe, Emi o fun wọn li ẹran, ki nwọn ki o le ma jẹ li oṣù kan tọ̀tọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Mo wà láàrin ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkirì, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’