Numbers 11:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu láti bá Mose sọ̀rọ̀. Ó sì mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára Mose, ó fi sára àwọn aadọrin olórí náà. Bí ẹ̀mí náà ti bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀, ṣugbọn wọn kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si sọkalẹ wá ninu awọsanma, o si bá a sọ̀rọ, o si mú ninu ẹmi ti o wà lara rẹ̀, o si fi i sara awọn ãdọrin àgba na: o si ṣe, nigbati ẹmi na bà lé wọn, nwọn sì sọtẹlẹ ṣugbọn nwọn kò ṣe bẹ̃ mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA sọ̀kalẹ̀ nínú ìkúùkù ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lárá Ẹ̀mí tó wà lára Mósè sí ara àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà náà, Ó sì sẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò ṣọtẹ́lẹ̀ mọ́.