Numbers 11:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Meji ninu àwọn olórí náà: Elidadi ati Medadi, kò bá wọn lọ, wọ́n dúró sinu àgọ́ wọn. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé wọn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn o kù meji ninu awọn ọkunrin na ni ibudó, orukọ ekini a ma jẹ́ Eldadi, orukọ ekeji Medadi: ẹmi na si bà lé wọn; nwọn si mbẹ ninu awọn ti a kà, ṣugbọn nwọn kò jade lọ si agọ́: nwọn si nsọtẹlẹ ni ibudó.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Élídádì àti Médádì kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin (70) àgbààgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ ṣíbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì ṣọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.