Numbers 11:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sì rán ìjì ńlá jáde, ó kó àwọn ẹyẹ kéékèèké kan wá láti etí òkun, wọ́n bà sí ẹ̀gbẹ́ ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. Wọn kò fò ju igbọnwọ meji lọ sílẹ̀, wọ́n wà ní ẹ̀yìn ibùdó káàkiri ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Afẹfẹ kan si ti ọdọ OLUWA jade lọ, o si mú aparò lati okun wá, o si dà wọn si ibudó, bi ìwọn ìrin ijọ́ kan ni ìha ihin, ati bi ìwọn ìrin ijọ́ kan ni ìha ọhún yi ibudó ká, ni ìwọn igbọnwọ meji lori ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ OLÚWA ó sì kó àparò wá láti inú òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká.