Numbers 11:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn, pé àwọn kò rí ẹran jẹ bí ìgbà tí àwọn wà ní Ijipti. Àwọn ọmọ Israẹli pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún àìrẹ́ran jẹ. Wọ́n ń sọ pé, “Ó mà ṣe o, a kò rí ẹran jẹ!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn adalú ọ̀pọ enia ti o wà pẹlu wọn ṣe ifẹkufẹ: awọn ọmọ Israeli pẹlu si tun sọkun wipe, Tani yio fun wa li ẹran jẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ́ wọn fi ìtara bèèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí!