Numbers 11:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan náà a máa lọ kó wọn láàárọ̀, wọn á lọ̀ ọ́ tabi kí wọn gún un lódó láti fi ṣe ìyẹ̀fun. Wọn á sè é ninu ìkòkò, wọn á fi ṣe bíi àkàrà, adùn rẹ̀ sì dàbí ti àkàrà dídùn tí a fi òróró olifi dín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia na a ma lọ kakiri, nwọn a si kó o, nwọn a si lọ̀ ọ ninu ọlọ, tabi nwọn a si gún u ninu odó, nwọn a si sè e ninu ìkoko, nwọn a si fi din àkara: itọwò rẹ̀ si ri bi itọwò àkara oróro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le ṣè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe.