Numbers 12:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí n óo sọ yìí: Nígbà tí àwọn wolii wà láàrin yín, èmi a máa fi ara hàn wọ́n ninu ìran, èmi a sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ lójú àlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi: “Bí wòlíì OLÚWA bá wà láàrin yín Èmi OLÚWA a máa fara à mi hàn án ní ojúran, Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.