Numbers 13:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ ṣe akiyesi bóyá ilẹ̀ náà dára tabi kò dára, ati pé bóyá àwọn eniyan ibẹ̀ ń gbé inú àgọ́ ninu ìlú tí ó tẹ́jú tabi ìlú olódi ni ìlú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi ilẹ na ti nwọn ngbé ti ri, bi didara ni bi buburu ni; ati bi ilu ti nwọn ngbé ti ri, bi ninu agọ́ ni, tabi ninu ilu odi;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi?