Numbers 13:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wò bóyá ilẹ̀ náà jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú, ẹ wò ó bóyá igi wà níbẹ̀ tabi kò sí. Ẹ múra gírí kí ẹ sì mú ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀.” (Àkókò náà sì jẹ́ àkókò àkọ́so àjàrà.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi ilẹ na ti ri, bi ẹlẹtu ni tabi bi aṣalẹ̀, bi igi ba mbẹ ninu rẹ̀, tabi kò sí. Ki ẹnyin ki o si mu ọkàn le, ki ẹnyin si mú ninu eso ilẹ na wá. Njẹ ìgba na jẹ́ akokò pipọn akọ́so àjara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èṣo àjàrà gíréépù.)