Numbers 13:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣikolu, wọn gé ṣiiri àjàrà kan tí ó ní èso. Ṣiiri àjàrà yìí tóbi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé àwọn meji ni wọ́n fi ọ̀pá gbé e. Wọ́n sì mú èso pomegiranate ati èso ọ̀pọ̀tọ́ wá pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dé odò Eṣkolu, nwọn si rẹ́ ọwọ́ àjara kan, ti on ti ìdi eso-àjara kan lati ibẹ̀ wá, awọn enia meji si fi ọpá rù u; nwọn si mú ninu eso-pomegranate, ati ti ọpọtọ́ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Éṣíkólù, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èṣo àjàrà gíréèpù kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èṣo pomegíránétì àti èṣo ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú.