Numbers 13:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Amaleki ń gbé ìhà gúsù ilẹ̀ náà. Àwọn ará Hiti, ará Jebusi ati àwọn ará Amori ń gbé àwọn agbègbè olókè. Àwọn ará Kenaani sì ń gbé lẹ́bàá òkun ati ní agbègbè Jọdani.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Ámálékì ń gbé ní ilẹ̀ Gúsù; àwọn ará Hítì, àwọn ará Jébúsì àti àwọn ará Ámórì ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kénánì sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jọ́dánì.”