Numbers 13:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ wò. Wọ́n ní, “Ilẹ̀ tí ń jẹ àwọn eniyan inú rẹ̀ ni ilẹ̀ náà, gbogbo àwọn tí a rí níbẹ̀ ṣígbọnlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mú ìhin buburu ti ilẹ na, ti nwọn ti ṣe amí wá fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ ti imu awọn enia rẹ̀ jẹ ni; ati gbogbo enia ti awa ri ninu rẹ̀ jẹ́ enia ti o ṣigbọnlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ yẹ̀ wò. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì sígbọnlẹ̀.