Numbers 14:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo ti kọ̀ mí sílẹ̀ pẹ́ tó. Yóo ti pẹ́ tó kí wọ́n tó máa gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Awọn enia yi yio ti kẹgàn mi pẹ tó? yio si ti pẹ tó ti nwọn o ṣe alaigbà mi gbọ́, ni gbogbo iṣẹ-àmi ti mo ṣe lãrin wọn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún Mósè pé: “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàrin wọn?