Numbers 14:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘OLUWA kì í tètè bínú, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé ji eniyan, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà. A máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘OLÚWA lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró sinsin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jìn. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’