Numbers 14:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo wọn ń kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ó sàn fún wa kí á kúkú kú sí Ijipti tabi ní aṣálẹ̀ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni: gbogbo ijọ si wi fun wọn pe, Awa iba kuku ti kú ni ilẹ Egipti! tabi awa iba kú li aginjù yi!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì sì kùn sí Mósè àti Árónì, gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì wí fún wọn pé; “Àwa ì bá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Éjíbítì. Tàbí kí a kúkú kú sínú ihà yìí.