Numbers 14:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ogoji ọdún. Ọdún kọ̀ọ̀kan yóo dípò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ninu ogoji ọjọ́ tí àwọn amí fi wo ilẹ̀ náà. Ẹ óo rí ibinu mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi iye ọjọ́ ti ẹnyin fi rìn ilẹ na wò, ani ogoji ọjọ́, ọjọ́ kan fun ọdún kan, li ẹnyin o rù ẹ̀ṣẹ nyin, ani ogoji ọdún, ẹnyin o si mọ̀ ibà ileri mi jẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi.