Numbers 15:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
bí gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá ṣẹ̀, láìmọ̀, wọn óo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, bi a ba fi aimọ̀ ṣe ohun kan ti ijọ kò mọ̀, ki gbogbo ijọ ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá fun ẹbọ sisun, fun õrùn didùn si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀, gẹgẹ bi ìlana na, ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá wáyé láìròtẹ́lẹ̀ láì jẹ́ pé ìjọ ènìyàn mọ̀ sí i, nígbà náà ni kí gbogbo ìjọ ènìyàn mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan wá fún ẹbọ sísun bí òórùn dídùn sí OLÚWA, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà, pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.