Numbers 15:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe oko jọnwọnjọnwọn sí etí aṣọ wọn ní ìrandíran wọn; kí wọ́n sì ta okùn aláwọ̀ aró mọ oko jọnwọnjọnwọn kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si fi aṣẹ fun wọn ki nwọn ki o ṣe wajawaja si eti aṣọ wọn ni iran-iran wọn, ati ki nwọn ki o si fi ọjábulẹ alaró si wajawaja eti aṣọ na:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé: ‘Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan.