Numbers 16:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ní, “O mú wa wá láti ilẹ̀ ọlọ́ràá Ijipti tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, o fẹ́ wá pa wá sinu aṣálẹ̀ yìí, sibẹ kò tó ọ, o tún fẹ́ sọ ara rẹ di ọba lórí gbogbo wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ohun kekere ha ni ti iwọ mú wa gòke lati ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin wá, lati pa wa li aginjù, ti iwọ fi ara rẹ jẹ́ alade lori wa patapata?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò ha tó gẹ́ ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú ihà yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di OLÚWA lé wa lórí bí?