Numbers 16:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLUWA pé, “OLUWA, má ṣe gba ẹbọ àwọn eniyan wọnyi. N kò ṣe ibi sí ẹnikẹ́ni ninu wọn bẹ́ẹ̀ ni ń kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnikẹ́ni wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si binu gidigidi, o si wi fun OLUWA pe, Máṣe kà ẹbọ wọn si: emi kò gbà kẹtẹkẹtẹ kan lọwọ wọn, bẹ̃li emi kò pa ẹnikan wọn lara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLÚWA pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!”