Numbers 16:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si doju wọn bolẹ, nwọn wipe, Ọlọrun, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ọkunrin kan ha le ṣẹ̀, ki iwọ ki o si binu si gbogbo ijọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Mósè àti Árónì dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mi gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣẹ̀?”