Numbers 16:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan náà bá kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu pẹlu aya ati àwọn ọmọ wọn jáde wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn si gòke lọ kuro nibi agọ́ Kora, Datani ati Abiramu, ni ìha gbogbo: Datani ati Abiramu si jade, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ wọn, ati awọn aya wọn, ati awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn wẹ́wẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù. Dátanì àti Ábírámù jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn.