Numbers 16:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Nisinsinyii ni ẹ óo mọ̀ pé èmi kọ́ ni mo yan ara mi ṣugbọn OLUWA ni ó rán mi láti ṣe gbogbo ohun tí mò ń ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe OLUWA li o rán mi lati ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi; ati pe emi kò ṣe wọn lati inu ara mi wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé OLÚWA ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe.