Numbers 16:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni, alufaa pé kí ó kó àwọn àwo turari wọ̀n-ọn-nì kúrò láàrin àjókù àwọn eniyan náà. Kí ó sì da iná inú wọn káàkiri jìnnà jìnnà nítorí àwọn àwo turari náà jẹ́ mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun Eleasari ọmọ Aaroni alufa, pe ki o mú awo-turari wọnni kuro ninu ijóna, ki iwọ ki o si tu iná na ká sọhún; nitoripe nwọn jẹ́ mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri síbi tó jìnnà.