Numbers 16:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ó mú àwo turari àwọn ọkunrin tí wọ́n kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ, nítorí níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti mú wọn wá siwaju OLUWA, wọ́n ti di mímọ́. Èyí yóo sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awo-turari ti awọn ẹlẹṣẹ wọnyi si ọkàn ara wọn, ni ki nwọn ki o fi ṣe awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: nitoriti nwọn mú wọn wá siwaju OLUWA, nitorina ni nwọn ṣe jẹ́ mimọ́: nwọn o si ma ṣe àmi fun awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni àwo tùràrí àwọn tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí ẹ gún àwo tùràrí yìí, kí ẹ sì fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, wọ́n jẹ́ mímọ́ nítorí pé wọ́n ti mú wọn wá ṣíwájú OLÚWA. Kí wọ́n jẹ́ àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”