Numbers 16:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ma ṣe ohun iranti fun awọn ọmọ Israeli, ki alejò kan, ti ki iṣe irú-ọmọ Aaroni, ki o máṣe sunmọtosi lati mú turari wá siwaju OLUWA; ki o má ba dabi Kora, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀: bi OLUWA ti wi fun u lati ọwọ́ Mose wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ṣe sọ láti ẹnu Mósè. Èyí yóò jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ẹlòmíràn yàtọ̀ sí irú ọmọ Árónì kò gbọdọ̀ jó tùràrí níwájú OLÚWA, ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò dàbí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.