Numbers 16:46 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo turari rẹ, fi ẹ̀yinná sinu rẹ̀ láti orí pẹpẹ kí o sì fi turari sí i. Ṣe kíá, lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan náà láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí ibinu OLUWA ti ru, àjàkálẹ̀ àrùn sì ti bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun Aaroni pe, Mú awo-turari kan, ki o si fi iná sinu rẹ̀ lati ori pẹpẹ nì wá, ki o si fi turari lé ori rẹ̀, ki o si yára lọ sọdọ ijọ, ki o si ṣètutu fun wọn: nitoriti ibinu jade lati ọdọ OLUWA lọ; iyọnu ti bẹ̀rẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì sọ fún Árónì pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárin ìjọ ènìyàn láti ṣètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú OLÚWA ti jáde, àjàkálẹ̀-àrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”