Numbers 16:47 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Mose. Ó mú àwo turari rẹ̀, ó sáré lọ sí ààrin àwọn eniyan náà. Nígbà tí ó rí i pé àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ́ sílẹ̀, ó fi turari sí i, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aaroni si mú awo-turari bi Mose ti fi aṣẹ fun u, o si sure lọ sãrin ijọ; si kiyesi i, iyọnu ti bẹ̀rẹ na lãrin awọn enia: o si fi turari sinu rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn enia na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Árónì ṣe bí Mósè ti wí, ó sáré lọ sí àárin àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrin wọn, ṣùgbọ́n Árónì fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.