Numbers 17:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ fún Mose, pé, “Dá ọ̀pá Aaroni pada siwaju Àpótí Ẹ̀rí, kí ó lè jẹ́ àmì ìkìlọ̀ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ Israẹli, kí wọ́n sì lè dẹ́kun kíkùn tí wọn ń kùn sí mi, kí wọ́n má baà kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ọpá Aaroni pada wa siwaju ẹrí, lati fi pamọ́ fun àmi fun awọn ọlọ̀tẹ nì; ki iwọ ki o si gbà kikùn wọn kuro lọdọ mi patapata ki nwọn ki o má ba kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Mú ọ̀pá Árónì padà wá ṣíwájú Ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmìn fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má baà kú.”