Numbers 18:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn àkọ́so tí ó pọ́n ní ilẹ̀ náà tí wọn bá mú wá fún OLUWA yóo jẹ́ tìrẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu ilé rẹ lè jẹ ẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Akọ́so gbogbo ohun ti o wà ni ilẹ wọn, ti nwọn o mú fun OLUWA wá, tirẹ ni yio jẹ́; gbogbo ẹniti o mọ́ ni ile rẹ ni ki o jẹ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún OLÚWA yóò jẹ́ tìrẹ, Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́.