Numbers 18:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Gbogbo àwọn àkọ́bí eniyan tabi ti ẹranko tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, tìrẹ ni. Ṣugbọn o óo gba owó ìràpadà dípò àkọ́bí eniyan ati ti ẹranko tí ó bá jẹ́ aláìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo akọ́bi ninu gbogbo ohun alãye, ti nwọn o mú wa fun OLUWA, iba ṣe ti enia tabi ti ẹranko, ki o jẹ́ tirẹ: ṣugbọn rirà ni iwọ o rà akọ́bi enia silẹ, ati akọ́bi ẹran alaimọ́ ni ki iwọ ki o rà silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún OLÚWA, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́.