Numbers 18:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn òbí yóo ra àwọn ọmọ wọn pada nígbà tí wọ́n bá pé ọmọ oṣù kan. Owó ìràpadà wọn jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli marun-un. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́, èyí tíí ṣe ogún ìwọ̀n gera ni kí wọ́n fi wọ̀n ọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ti a o ràsilẹ, lati ẹni oṣù kan ni ki iwọ ki o ràsilẹ, gẹgẹ bi idiyelé rẹ, li owo ṣekeli marun, nipa ṣekeli ibi-mimọ́ (ti o jẹ́ ogun gera).
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọn ogún (20) gérà.