Numbers 18:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Gbogbo àwọn ẹbọ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi ni mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ, lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Èyí jẹ́ majẹmu pataki tí mo bá ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ dá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ẹbọ igbesọsoke ohun mimọ́ wọnni, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun OLUWA, ni mo ti fi fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: majẹmu iyọ̀ ni lailai niwaju OLUWA fun ọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohunkóhun tí a bá ti yà sọ́tọ̀ nínú ọrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n mú wá fún OLÚWA ni mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe déédé. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ láéláé níwájú OLÚWA fún ìwọ àti ọmọ rẹ.”