Numbers 18:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pe àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, ẹ̀yà ìdílé baba rẹ, pé kí wọn wà pẹlu rẹ, kí wọ́n sì máa jíṣẹ́ fún ọ nígbà tí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ bá ń ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Ẹ̀rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o sì mú àwọn ènìyàn rẹ ará Léfì láti ẹ̀yà ìran rẹ láti dàpọ̀ mọ́ ìwọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ níwájú Àgọ́ Ẹ̀rí.