Numbers 18:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìlànà ayérayé ni èyí fún arọmọdọmọ yín, wọn kò tún gbọdọ̀ ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ, awọn ni yio si ma rù ẹ̀ṣẹ wọn: ìlana lailai ni ni iran-iran nyin, ati lãrin awọn ọmọ Israeli, nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Léfì ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò ní gba ogún kankan láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.