Numbers 18:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí pé gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún mi ni mo ti fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìní. Ìdí sì nìyí tí mo fi sọ fun wọn pé wọn kò lè ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori idamẹwa awọn ọmọ Israeli, ti nwọn múwa li ẹbọ igbesọsoke fun OLUWA, ni mo ti fi fun awọn ọmọ Lefi lati ní: nitorina ni mo ṣe wi fun wọn pe, Nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdá kan nínú ìdá mẹ́wàá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí OLÚWA. Èyí ni mo wí nípa wọn: Wọn kò ní gba ogún kankan láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”