Numbers 18:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi pé, “Nígbà tí ẹ bá gba ìdámẹ́wàá tí OLUWA ti fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ óo san ìdámẹ́wàá ninu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si sọ fun awọn ọmọ Lefi, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbà idamẹwa ti mo ti fi fun nyin ni ilẹiní nyin lọwọ awọn ọmọ Israeli, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke ninu rẹ̀ wá fun OLUWA, idamẹwa ninu idamẹwa na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún àwọn ọmọ Léfì kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ OLÚWA.