Numbers 18:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ọrẹ yín wá fún OLUWA ninu ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá san fun yín. Ẹ óo mú ọrẹ tí ó jẹ́ ti OLUWA wá fún Aaroni alufaa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li ẹnyin pẹlu yio ma mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA ninu gbogbo idamẹwa nyin, ti ẹnyin ngbà lọwọ awọn ọmọ Israeli; ki ẹnyin ki o si mú ẹbọ igbesọsoke OLUWA ninu rẹ̀ tọ̀ Aaroni alufa wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún OLÚWA láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Láti ara ìdámẹ́wá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ OLÚWA fún Árónì àlùfáà.