Numbers 18:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò ní jẹ̀bi nígbà tí ẹ bá jẹ ẹ́, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti san ìdámẹ́wàá ninu èyí tí ó dára jù. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà sọ ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli di àìmọ́ nípa jíjẹ wọ́n láìsan ìdámẹ́wàá wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ óo kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin ki yio si rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ki ẹnyin ki o má ba kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ìpín tí ó dára jùlọ o kò ní jẹ̀bi lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ kò sì ní ba ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́, ìwọ kì yóò sì kú.’ ”