Numbers 18:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ti yan àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọ. Wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn fún OLUWA, wọn óo sì máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi fúnra mi ti yan àwọn arákùnrin rẹ tí í ṣe ọmọ Léfì kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, wọn jẹ́ ẹ̀bùn fún ọ, èyí ni a fún OLÚWA láti ṣe iṣẹ́ tí ó wà ní àgọ́ ìpàdé.