Numbers 18:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni yóò mójú tó iṣẹ́ àlùfáà yín fún gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ibi pẹpẹ àti ti ẹ̀yin aṣọ títa, ẹ ó sì máa ṣiṣẹ́ ibi pẹpẹ àti nínú aṣọ tí a ta. Mo fún ọ ní iṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Ṣùgbọ́n àlejò tí ó bá sún mọ́ tòòsí ibi ìyà sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni a ó pa.”