Numbers 19:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ó bá kó eérú náà jọ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli ati fún àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹniti o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: yio si jẹ́ ilana titilai, fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àwọn àlejò tí ó ń gbé láàrin wọn.