Numbers 19:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú, tí kò bá fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀, yóo sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin ọmọ Israẹli, nítorí kò fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀; ó sì jẹ́ aláìmọ́ sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ti o kú, ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, o bà agọ́ OLUWA jẹ́; ọkàn na li a o si ke kuro ninu Israeli: nitoriti a kò wọ́n omi ìyasapakan si i lara, alaimọ́ li o jẹ̀; aimọ́ rẹ̀ mbẹ lara rẹ̀ sibẹ̀,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ OLÚWA jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀.