Numbers 19:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ tí kò sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́, yóo jẹ́ aláìmọ́ sibẹ nítorí pé a kò tíì da omi ìwẹ̀nùmọ́ sí i lára. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹniti o ba jẹ́ alaimọ́, ti kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ, nitoriti o bà ibi-mimọ́ OLUWA jẹ́: a kò si ta omi ìyasapakan si i lara; alaimọ́ li on.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ OLÚWA jẹ́. A kò tíì fi omi ìwẹ̀nùmọ́sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́.