Numbers 2:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Reubẹni jẹ́ ẹgbaa marundinlọgọrin ó lé aadọta lé ní egbeje (151,450). Àwọn ni yóo máa tẹ̀lé ibùdó Juda nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Reubeni jẹ́ ẹgba marundilọgọrin o le ãdọtalelegbeje, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Rúbẹ́nì, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rún ó lé àádọ́tàlélégbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.